Acts 18:4-11

4Ó sì ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú Sinagọgu lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Giriki lọ́kàn padà.

5Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà. 6Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn mi mọ́: láti ìsinsin yìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”

7Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ọkùnrin kan tí a ń pé ní Titu Justu, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sinagọgu tímọ́tímọ́. 8Krisipu, olórí Sinagọgu, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀: àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọrinti, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitiisi wọn.

9 aOlúwa sì sọ fún Paulu lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, ṣá máa sọ, má sì ṣe pa ẹnu rẹ̀ mọ́: 10Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.” 11Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrín wọn.

Copyright information for YorBMYO